O ti pese ilu nla sile fun won (Heberu 11:16)
Jerusalem t'orun,
Orin mi ilu mi!
lle mi bi mba ku,
Ekun ibukun mi!
Egbe: Ibi ayo! Nigba wo ni,
Ngor' oju re,
Olorun mi?
Odi re ilu mi,
L'a fi pearl se l' oso
L'ekun re ndan fun 'yin
Wura ni ita re.
Orun ki ran nibe,
Beni ko s' osupa,
Ako wa iwonyi,
Kristi n' imole 'bę.
Nibe l'Oba mi wa,
T'a da le bi l' aiye
Angeli nkorin fun,
Nwon si nteriba fun.
Patriak' igbani,
Par' ayo won ni bę;
Awon woli, nwon nwo
Omo Alade won.
Nibe ni mo le ri,
Awon aposteli,
At' awon akorin,
ti nlu harpu wura.
Ni agbala won ni,
Ni awon martir' wa;
Nwon wo aso ala,
Ogo bo ogbe won.
T'e mi yi sa su mi,
Ti mo ngb' ago kedari!
Ko si 'ru yi l' oke,
nibę ni mo fẹ lọ.