"Nigbati nwon si de ibiti a npe ni Agbari, nibe ni won gbe kan A mo Agbelebu" (Luku 23:33)
At Calvary R.S.778
OP' ODUN ni mo ti lo lasan,
Ti ng ko naani p' Olugbala ku,
Laimo p' emi ni Jesu ku fun
Ni Kalfari.
Egbe: Mori aanu on ore-ofe,
Ati idariji ese gba;
Okan eru mi si d' omnira
Ni Kalfari.
Nip' or' Olorun mo m'eseemi,
Mo si wariri fun ese naa,
Tit' okan isako mi pada
Si Kalfari.
Motif ohun gbogbo fun Jesu,
Mo si ni On gege b'Oba mi;
Nisisiyi okan mi korin
Ti Kalfari.
Aa! ife t'o mu igbala wa,
Aa! or' ofe t'o mu U sokalę;
Aa! ogbun nla ti Olorun dii
Ni Kalfari.