"Omo enia de lati wa awon ti o nu" (Luku 19:10)
Amazing Grace S.S. & S. 892
ORE-OFE b'o ti dun to!
T'o gba em' aosi;
Moti sonu, o wa mi ri,
O si si mi loju.
Or' ofę ko mi ki ng beru,
O si l' eru mi lo;
B'ore-ofe naa ti han to
Nigba' mo ko gbagbo!
Opo ewu ati 'dekun,
Ni mo ti la koja;
Or'-ofe npa mi mo d'oni,
Y'o si sin mi de 'le.
Nje 'gbat' ara at' okan yi,
At'emi ba si pin,
Ngo gb' ayo' at' alaafia,
Loke orun lohun. Amin.