"Itanna Lili laarin (Orin Solomoni 2:2) egun"
Lily of the Valley S.S. & S. 104.
Moti ni Jesu l'ore
Oj' ohun gbogbo fun mi;
On nikan l' arewa ti okan mi fe,
On ni 'tanna ipa 'do
On ni Enikan naa
T'Ole wę mi nu kuro nin' ese mi;
Olutunu mi l' O ję, N'nu gbogbo 'banuję
Oni ki ng kaniyan mi le E lori,
On ni 'tanna ipa 'do, Irawo Owurọ;
On nikan l' arewa ti okan mi nfe
Egbe: Olutunu mi l' O ję,
N'nu gbogbo 'banuję;
Oni ki ng k'aniyan mi le E Iori
Oun ni 'tanna ipado, Irawo Owuro;
On nikan l' arewa ti okan mi nfe.
O gbe gbogbo 'banuję
Ati 'rora miru;
Oj'odi agbara mi nigba 'danwo;
Tori Re mo ko iwa Esę gbogbo sile,
Osif agbara Re gbe okan mi ro
Bi aiye tilę ko mi,
Ti Esu dan mi wo,
Jesu y'o mu mi de opin 'rin mi
On ni 'tanna ipa 'do,
Irawo Owuro,
On nikan l'arewa ti okan mi nfe.