"Oru mbo wa nigbati enikan li yio le sise" (Johannu 9:4)
Work for the Night is Coming S.S. & S. 778
SISE 'tori oru mbo! Sise Ii owuro
Sisę nigba 'iri nse, sisę n'nu 'tanna,
Sisę ki osan to po, sisę nigb' oorun nran,
Sise 'tori oru mbo, 'gba 'se o pari.
Sise 'tori oru mbo! Sisę losan gangan,
F' akoko rere fun 'se, isinmi daju;
F'olukuluku igba, ni nkan lati pamo;
Sise 'tori oru mbo, 'gba 'se o pari.
Sise 'tori oru mbo! Oorun ferę won a,
Sise 'gbati 'mole wa, ojo bu lo tan;
Sisę titi de opin, sisee titi d'ale;
Sise 'gbati 'le ba su, 'gba 'se o pari.