"Bi enikeni ba nsin Mi, ki o maa to mi lehin" (Johannu12:26)
O Jesus, I have Promised S.S. & S.606
MO ti se 'leri, Jesu,
Lati sin Ọ dopin; Maa wa lodo mi titi,
Baba mi, Ọre mi.
Emi ko beru ogun,
Bi 'Wo ba sunmo mi,
Emi ki y'o si sina,
B'O ba f' ona han mi.
Je ki ng mo p' O sunmo mi,
'Tori 'baje aiye;
Aiye fe gba okan mi,
Aiye fe tan mi je;
Ota yi mi kakiri,
Lode ati ninu;
Sugbon Jesu, sunmo mi,
Daabobo okan mi.
Je ki emi k'o maa gbo,
Ohun Re, Jesu mi,
Ninu igbi aiye yi,
Titi nigbagbogbo;
So mi, k'o da mi loju,
K'okan mi ni 'janu;
So, si mu mi gbo
Tire, 'Wo Olutoju mi.
'Wo ti se 'leri, Jesu,
F'awon t' o tele Q,
Pe ibikibi t' Owa,
L'awon yio si wa,
Mo ti se leri, Jesu,
Lati sin O dopin,
Je ki ng maa to O leehin,
Babami. Ore mì.
Je ki ng maa ri 'pase Re
Ki ng fe maa tele O,
Agbara Rę nikan ni,
Ti ng ba le tele O;
To mi, pe mi, si fá mi,
Di mi mu de opin,
Si gba mi si odo Re
Baba mi, Ore mi. Amin.