Tuesday, August 31, 2021

APATA AIYERAYE

 "Emi O fi o sinu palapala apata" (Eksodu 33:22)

Rock of Ages               S.S. & S.237



APATA aiyeraiye, 

Se ibi isadi mi; 

Je ki omi on eje 

To san lati iha Rę; 

Se iwosan fese mi, 

K'o si so mi di mimo.



Kii 'se ise owo mi 

L'ole mu ofin Re se; 

Bi'tara mi ko l' aare, 

T'omije mi nsan titi, 

Nwon ko to fun etutu, 

'Wo nikan l' o le gbala.



Ko s' ohun ti mo mu wa, 

Mo ro mo agbelebu; 

Mowa, k'O d' aso bo mi, 

Mo nwo O fun iranwo, 

Mo wa sib' orisun ni, 

We mi, Olugbala mi.



'Gbati emi mi ba nlo, 

Ti 'ku bap' oju mi de, 

Ti ng banlos' aiye aimo, 

Ti ng ri Oni 'to 'dajo, 

Apata aiyeraiye, 

Se ibi isadi mí. 

Amin.

NI KALFARI

 "Nigbati nwon si de ibiti a npe ni Agbari, nibe ni won gbe kan A mo Agbelebu" (Luku 23:33)

  At Calvary              R.S.778

   



OP' ODUN ni mo ti lo lasan, 

Ti ng ko naani p' Olugbala ku, 

Laimo p' emi ni Jesu ku fun 

Ni Kalfari.



Egbe: Mori aanu on ore-ofe, 

           Ati idariji ese gba; 

           Okan eru mi si d' omnira

           Ni Kalfari.



Nip' or' Olorun mo m'eseemi, 

Mo si wariri fun ese naa, 

Tit' okan isako mi pada 

Si Kalfari.



Motif ohun gbogbo fun Jesu,  

Mo si ni On gege b'Oba mi; 

Nisisiyi okan mi korin 

Ti Kalfari.



Aa! ife t'o mu igbala wa, 

Aa! or' ofe t'o mu U sokalę; 

Aa! ogbun nla ti Olorun dii 

Ni Kalfari.

MOTI NI JESU LORE


"Itanna Lili laarin (Orin Solomoni 2:2) egun"

Lily of the Valley                  S.S. & S. 104.



Moti ni Jesu l'ore

Oj' ohun gbogbo fun mi;

On nikan l' arewa ti okan mi fe,

 On ni 'tanna ipa 'do

On ni Enikan naa 

T'Ole wę mi nu kuro nin' ese mi;

Olutunu mi l' O ję, N'nu gbogbo 'banuję

Oni ki ng kaniyan mi le E lori,

On ni 'tanna ipa 'do, Irawo Owurọ;

On nikan l' arewa ti okan mi nfe


Egbe: Olutunu mi l' O ję,

           N'nu gbogbo 'banuję;

           Oni ki ng k'aniyan mi le E Iori

           Oun ni 'tanna ipado, Irawo Owuro;

           On nikan l' arewa ti okan mi nfe. 



O gbe gbogbo 'banuję

Ati 'rora miru;

Oj'odi agbara mi nigba 'danwo;

Tori Re mo ko iwa Esę gbogbo sile,

Osif agbara Re gbe okan mi ro

Bi aiye tilę ko mi,

Ti Esu dan mi wo,

Jesu y'o mu mi de opin 'rin mi 

On ni 'tanna ipa 'do,

Irawo Owuro, 

On nikan l'arewa ti okan mi nfe.

MO FE O 'GBA GBOGBO

 "Emio fe O, Oluwa, agbara mi" (Orin Dafidi 18:1) 

I Need Thee Every Hour              S. S. & S. 577




Mo fe O'gbagbogbo, 

Olugbala, 

Ohun pele Re; 

ni nmu 'laafia wa.


Egbe: Mo fe O, 

           Aa! mo fe O, 

          Ni wakati gbogbo, 

          Bukun mi Olugbala, 

          Mo wa 'do Re.



Mo fe O'gbagbogbo, 

Gbe nitosi, 

'Danwo ko ni 'pa mo, 

' Gbat' O wa nitosi.



Mo fe O' gbagbogbo, 

Ninu 'ponju, 

Yara wa ba mi gbe, 

'Tor' asan l' aiye.



Mo fe O'gbagbogbo, 

Eni Mimo, 

Kin saa maa je Tire, 

k'O si maa bukun Mi. 


Amin.

Monday, August 30, 2021

NGO SUN MO OLORUN

 "Awon enia... sunmo odo Re" (Orin Dafidi 148:14)




Nearer, My God, to Thee                   S.S. & S. 681



NGO sunm' O, Olorun, ngo sunmo O;

B'o tile se 'ponju, l'o mu mi wa; 

Sibe, orin mi ję, ngo sunm' O, Qlorun, 

Ngo sunm' O, Olorun, ngo sunmo O.



Ni Ona ajo mi, bi 'lę ba su, 

Bi okuta siję irori mi;

Sibę, nin' ala mi, ngo sunm' Q, 

Qlorun Ngo sunm' Q, Qlorun, ngo sunmo Q.



Nibe je ki ng r' ona t' o lo s'orun; 

Gbogb' ohun t' o fun mi nin' aanu Re. 

Angel' lati pe mi, ngo sunm' Ọ Olorun, 

Ngo sunm' Q, Olorun, ngo sunmo Ọ.



Nje 'gbati mo ba ji, em' o yin Q; 

Ngo f' akete mi se Betel fun Q: 

Bee ninu osi mi, ngo sunm' Q, Olorun, 

Ngo sunm' Q, Olorun, ngo sunmọ Ọ.


Gba' nb ba fi ayo lo soke orun, 

 T'o ga ju oorun lo, soke giga; 

Orin mi yio je, ngo sunm' Q, Olorun, 

Ngo sunm' Q, Olorun, ngo sunmọ Ọ.

KIN FE O SI

 "Beeni Oluwa; Iwo mo pe, mo feran Re" (Johannu 21:15)



More Love to Thee, O Christ                S.S. & S. 632



KI ng fe O sii, Kristi! Kin fe O sii; 

Gb'adura ti mo ngba lor' eekun mi 

Eyi ni ebę mi; ki ng fe O sii, Kristi! 

Kin fe O sii! ki ng fe O sii!



Leçkan, 'ohun aiye ni mo ntoro; Nisisiyi,

 'Wo nikan ni mo nwa; Eyi l'adura mi; 

ki ng fe Ọ sii, Kristi! 

Kin fe O sii! ki ng fe Ọ sii!



Je ki 'banuję de, ati 'rora, 

Didun l' ojisę ati 'se won.

'Gba' nwon mba mi korin, ki ng fe O sii 

Kristi! King fe O sii! ki ni fe Ọ sii!



"Nje, opin emi mi y'o wi 'yin Re 

Eyi ni y'o je oro 'kehin re, 

Adura naa y'o ję; ki ng fe; O sii, Kristi! 

Kin fe O sii! ki ng fe O sii! Amin.

MO N TESIWAJU LO

 "MONTESIWAJUL'ONANAA" Higher Ground


Monte siwaju l'o na naa,

mo ngo ke Sii lojojumo, 

mo ngbadura bi mo ti nlọ, 

Oluwa joo gbe mi soke.



Egbe: Oluwa joo, gbe mi soke, 

          Fami lo si ibi giga  

          Apata to ga ju yi lo, 

          Oluwa joo gbemi soke.



Ife okan mi ko duro 

laa rin 'ye meji at' eru 

Awon miran ngbe niberu, 

Adura mi joo gbe mi soke.



Mo fe ki nga ju aiye lo 

B' esu ti le ngbogun ti mi, 

Mo fi gbogbo k' orin ayo. 

Ti awon mimo nko loke.



Mo fe de 'bi giga julọ

ki nriran n'nu og didan, 

Ngo gbadura t' ngo fi d' orun,

Oluwa joo gbe mi soke.

GBA AIYE MI OLUWA

  "Bio se emi ati ile mi ni, Oluwa li awa o maa sin" (Josua 24:15)      Take my Life, and Let it be             G. H. 12 GBA aiye ...