Tuesday, August 31, 2021

APATA AIYERAYE

 "Emi O fi o sinu palapala apata" (Eksodu 33:22)

Rock of Ages               S.S. & S.237



APATA aiyeraiye, 

Se ibi isadi mi; 

Je ki omi on eje 

To san lati iha Rę; 

Se iwosan fese mi, 

K'o si so mi di mimo.



Kii 'se ise owo mi 

L'ole mu ofin Re se; 

Bi'tara mi ko l' aare, 

T'omije mi nsan titi, 

Nwon ko to fun etutu, 

'Wo nikan l' o le gbala.



Ko s' ohun ti mo mu wa, 

Mo ro mo agbelebu; 

Mowa, k'O d' aso bo mi, 

Mo nwo O fun iranwo, 

Mo wa sib' orisun ni, 

We mi, Olugbala mi.



'Gbati emi mi ba nlo, 

Ti 'ku bap' oju mi de, 

Ti ng banlos' aiye aimo, 

Ti ng ri Oni 'to 'dajo, 

Apata aiyeraiye, 

Se ibi isadi mí. 

Amin.

NI KALFARI

 "Nigbati nwon si de ibiti a npe ni Agbari, nibe ni won gbe kan A mo Agbelebu" (Luku 23:33)

  At Calvary              R.S.778

   



OP' ODUN ni mo ti lo lasan, 

Ti ng ko naani p' Olugbala ku, 

Laimo p' emi ni Jesu ku fun 

Ni Kalfari.



Egbe: Mori aanu on ore-ofe, 

           Ati idariji ese gba; 

           Okan eru mi si d' omnira

           Ni Kalfari.



Nip' or' Olorun mo m'eseemi, 

Mo si wariri fun ese naa, 

Tit' okan isako mi pada 

Si Kalfari.



Motif ohun gbogbo fun Jesu,  

Mo si ni On gege b'Oba mi; 

Nisisiyi okan mi korin 

Ti Kalfari.



Aa! ife t'o mu igbala wa, 

Aa! or' ofe t'o mu U sokalę; 

Aa! ogbun nla ti Olorun dii 

Ni Kalfari.

MOTI NI JESU LORE


"Itanna Lili laarin (Orin Solomoni 2:2) egun"

Lily of the Valley                  S.S. & S. 104.



Moti ni Jesu l'ore

Oj' ohun gbogbo fun mi;

On nikan l' arewa ti okan mi fe,

 On ni 'tanna ipa 'do

On ni Enikan naa 

T'Ole wę mi nu kuro nin' ese mi;

Olutunu mi l' O ję, N'nu gbogbo 'banuję

Oni ki ng kaniyan mi le E lori,

On ni 'tanna ipa 'do, Irawo Owurọ;

On nikan l' arewa ti okan mi nfe


Egbe: Olutunu mi l' O ję,

           N'nu gbogbo 'banuję;

           Oni ki ng k'aniyan mi le E Iori

           Oun ni 'tanna ipado, Irawo Owuro;

           On nikan l' arewa ti okan mi nfe. 



O gbe gbogbo 'banuję

Ati 'rora miru;

Oj'odi agbara mi nigba 'danwo;

Tori Re mo ko iwa Esę gbogbo sile,

Osif agbara Re gbe okan mi ro

Bi aiye tilę ko mi,

Ti Esu dan mi wo,

Jesu y'o mu mi de opin 'rin mi 

On ni 'tanna ipa 'do,

Irawo Owuro, 

On nikan l'arewa ti okan mi nfe.

MO FE O 'GBA GBOGBO

 "Emio fe O, Oluwa, agbara mi" (Orin Dafidi 18:1) 

I Need Thee Every Hour              S. S. & S. 577




Mo fe O'gbagbogbo, 

Olugbala, 

Ohun pele Re; 

ni nmu 'laafia wa.


Egbe: Mo fe O, 

           Aa! mo fe O, 

          Ni wakati gbogbo, 

          Bukun mi Olugbala, 

          Mo wa 'do Re.



Mo fe O'gbagbogbo, 

Gbe nitosi, 

'Danwo ko ni 'pa mo, 

' Gbat' O wa nitosi.



Mo fe O' gbagbogbo, 

Ninu 'ponju, 

Yara wa ba mi gbe, 

'Tor' asan l' aiye.



Mo fe O'gbagbogbo, 

Eni Mimo, 

Kin saa maa je Tire, 

k'O si maa bukun Mi. 


Amin.

Monday, August 30, 2021

NGO SUN MO OLORUN

 "Awon enia... sunmo odo Re" (Orin Dafidi 148:14)




Nearer, My God, to Thee                   S.S. & S. 681



NGO sunm' O, Olorun, ngo sunmo O;

B'o tile se 'ponju, l'o mu mi wa; 

Sibe, orin mi ję, ngo sunm' O, Qlorun, 

Ngo sunm' O, Olorun, ngo sunmo O.



Ni Ona ajo mi, bi 'lę ba su, 

Bi okuta siję irori mi;

Sibę, nin' ala mi, ngo sunm' Q, 

Qlorun Ngo sunm' Q, Qlorun, ngo sunmo Q.



Nibe je ki ng r' ona t' o lo s'orun; 

Gbogb' ohun t' o fun mi nin' aanu Re. 

Angel' lati pe mi, ngo sunm' Ọ Olorun, 

Ngo sunm' Q, Olorun, ngo sunmo Ọ.



Nje 'gbati mo ba ji, em' o yin Q; 

Ngo f' akete mi se Betel fun Q: 

Bee ninu osi mi, ngo sunm' Q, Olorun, 

Ngo sunm' Q, Olorun, ngo sunmọ Ọ.


Gba' nb ba fi ayo lo soke orun, 

 T'o ga ju oorun lo, soke giga; 

Orin mi yio je, ngo sunm' Q, Olorun, 

Ngo sunm' Q, Olorun, ngo sunmọ Ọ.

KIN FE O SI

 "Beeni Oluwa; Iwo mo pe, mo feran Re" (Johannu 21:15)



More Love to Thee, O Christ                S.S. & S. 632



KI ng fe O sii, Kristi! Kin fe O sii; 

Gb'adura ti mo ngba lor' eekun mi 

Eyi ni ebę mi; ki ng fe O sii, Kristi! 

Kin fe O sii! ki ng fe O sii!



Leçkan, 'ohun aiye ni mo ntoro; Nisisiyi,

 'Wo nikan ni mo nwa; Eyi l'adura mi; 

ki ng fe Ọ sii, Kristi! 

Kin fe O sii! ki ng fe Ọ sii!



Je ki 'banuję de, ati 'rora, 

Didun l' ojisę ati 'se won.

'Gba' nwon mba mi korin, ki ng fe O sii 

Kristi! King fe O sii! ki ni fe Ọ sii!



"Nje, opin emi mi y'o wi 'yin Re 

Eyi ni y'o je oro 'kehin re, 

Adura naa y'o ję; ki ng fe; O sii, Kristi! 

Kin fe O sii! ki ng fe O sii! Amin.

MO N TESIWAJU LO

 "MONTESIWAJUL'ONANAA" Higher Ground


Monte siwaju l'o na naa,

mo ngo ke Sii lojojumo, 

mo ngbadura bi mo ti nlọ, 

Oluwa joo gbe mi soke.



Egbe: Oluwa joo, gbe mi soke, 

          Fami lo si ibi giga  

          Apata to ga ju yi lo, 

          Oluwa joo gbemi soke.



Ife okan mi ko duro 

laa rin 'ye meji at' eru 

Awon miran ngbe niberu, 

Adura mi joo gbe mi soke.



Mo fe ki nga ju aiye lo 

B' esu ti le ngbogun ti mi, 

Mo fi gbogbo k' orin ayo. 

Ti awon mimo nko loke.



Mo fe de 'bi giga julọ

ki nriran n'nu og didan, 

Ngo gbadura t' ngo fi d' orun,

Oluwa joo gbe mi soke.

JERUSALEM T'ORUN


O ti pese ilu nla sile fun won (Heberu 11:16)





Jerusalem t'orun,

Orin mi ilu mi! 

lle mi bi mba ku, 

Ekun ibukun mi!



Egbe: Ibi ayo! Nigba wo ni, 

          Ngor' oju re,

          Olorun mi?



Odi re ilu mi, 

L'a fi pearl se l' oso 

L'ekun re ndan fun 'yin 

Wura ni ita re.



Orun ki ran nibe,

Beni ko s' osupa,

Ako wa iwonyi, 

Kristi n' imole 'bę.



Nibe l'Oba mi wa, 

T'a da le bi l' aiye 

Angeli nkorin fun, 

Nwon si nteriba fun.



Patriak' igbani, 

Par' ayo won ni bę;

Awon woli, nwon nwo

Omo Alade won. 



Nibe ni mo le ri, 

Awon aposteli,

At' awon akorin, 

ti nlu harpu wura.



Ni agbala won ni, 

Ni awon martir' wa; 

Nwon wo aso ala, 

Ogo bo ogbe won.



T'e mi yi sa su mi, 

Ti mo ngb' ago kedari! 

Ko si 'ru yi l' oke, 

nibę ni mo fẹ lọ.

EFUN PE NAA KIKAN

 "Emi Oluwa Jehofa mbę lara mi" (Isaiah 61:1) 

Blow Ye the Trumpet, Blow               H.C.1111




EFUN 'pe naa kikan

Ipe Ihinrere;

K' dun jakejado,

L'eti gbogbo eda;



Egbe:  Odun idasile ti de; 

            Pada, elęsę pada.

            Fun 'pet' Odagutan 

            T'a ti pa etutu;

Ję ki agbaiye mo 

Agbara eję Rę;

dun idasile ti de,

Pada, elęsę, pada.



Enyin eruese, 

E so 'ra nyin d'omo; 

Lowo Kristi Jesu 

Egba ominira nyin; 

odun idasilę ti de, 

Pada, elęsę, pada.



Olori Alufaa, 

L'Olugbala ise; 

O fi'ra Rerubo 

Arukun, aruda; 

Odun idasilę ti de, 

Pada, elęsę, pada.

IGBE TA SO KE LATI LE OKUNKUN

 "Rekoja wa si Makedonia, ki o si ran wa lowo"

(Ise Awon Aposteli 16:9)     R.S. 628




IGBE ta soke lati 'lę okunkun

Ran 'mole,.. Ran' 'mole!

Ainiye okan enia mbe fun 'gbala,

Ran 'mole... Ran 'mole!



Egbe: Ran 'mole,,, mole ihin,,, re,,,

          Je k'o ran,.. si gbogb' aiye



Angbo igbe awon ti nsegbe loni,

Ran 'mole, " Ran 'mole!

Am'ebun ife wa wa fun 'isę Rę,

Ran 'mole,.. Ran 'mole!



Je k' a gbadura k' ore-ofe po sii,

Ran 'mole,,, Ran 'mole! 

K'emi jesu le gbe l'okan wa gbogbo, 

Ran 'mole, ., Ran 'mole!.




Maje k' aarę mu wa ni 'se Oluwa,

 Ran 'mole,,, Ran 'mole! 

K'a le so 'eso fun ade wa'ioke,

Ran 'mole, "Ran 'mole!

EKUN KO LE GBA MI

 "Ore-ofe li a ti fi gba nyin laa" (Efesu 2:5)


S.S. & S. 337      Weeping Will Not Save Me




EKUN ko le gba mi; 

bi mo le f ekun we 'ju 

Ko le mu eru mi tan, 

ko le we ese mi nu, 

Ekun ko le gba mi.



Jesu sun O ku fun mi, 

O jiya lori igi, 

Latí so mi d'omnira, 

On l'o le gba mi la.



Ise ko le gba mi; 

isę mi t'o dara ju, o ima.

Iro mi t'o mo julo, 

ko le s' okan mi d'




Duro ko le gba mi, 

enit' o sonu ni mi

L' eti mi aanu nke pe, 

bi mo ba duro

Sengoku,

Duro ko le gba mi.



Igbagbo le gba mi, 

je ki ng gbękęl' Omo Re, 

je; ki ng gbekele 'se Rę, 

je ki ng sa si apa Re, 

Igbagbo le gba mi.

ETUN WON KO FUN MI KI NI GBO

 "Oro wonni ti Mo so fun nyin, eni iye si ni" (Johannu 6:63)


S.S.& S. 357        Wonderful Words of Life




ETUN won ko fun mi ki ni'gbo

Oro 'yanu ti 'ye! 

Je king si tun ewa won o,

Oro 'yanu ti ye!



Oro 'ye at' ewa, ti nko mi ni 'gbagbo!


Oro didun! oro 'yanu!

Oro 'yanu ti'ye." 

Oro didunl Oro. 'yanu! 

Oro 'yanu ti 'ye.


Kristi nikan l' o nfi funni, 

Oro 'yanu ti 'ye! 

Oro 'yanu ti'ye, Lofe l'a fifun wa, k'o le to wa s'orun!


Elese, gbo 'pe ife naa,


'Gbe ohun Ihinrere naa, Oro 'yanu ti 'ye! Fi'gbala lo gbogbo enia, Oro 'yanu ti'ye! Jesu Olugbala, we wa mo titi lai!

KILO LE WE SE MINU

"Eję Jesu Kristi ni nwę wa nu" (1 Johannu 1:7)


S.S. & S.874       Nothing but the Blood 




KIL' O le we 'se mi nu, 

Ko si, lehin eję Jesu; 

Kil' 0 tun le wo mi san, 

Ko si, lehin eję Jesu.



Aa! eje 'yebiye,

T'o mu mi fun bii sno, 

Ko si 'sun miran mo, 

Ko si, lehin eję Jesu.



Fun 'wenumo mi, ng'ko ri, 

Nkan mii, lehin eję Jesu; 

Ohun ti mo gbekele 

Fun 'dariji, l'eje Jesu.



Etutu f' ese ko si.

Ko si, lehin eje Jesu, 

Ise rere kan ko si, 

Ko si, lehin eje Jesu.



Gbogbo igękele mi, 

Ireti mi, l'eje Jesu; 

Gbogbo ododo mi ni, 

Eję, kiki eję Jesu.



WO TI TO JESU FAGBARA WENUMO

 "Nwon si so won di funfun ninu eje Odo-aguntan naa"  (Ifihan 7:14)


Have You Been to Jesus                      S.S. S.379




'WO ti to Jesu f' agbara 'wenumo? 

Awe nin' ej' Odagutan? 

Iwo hangbekele ore-ofe Re? 

Awe o nin' ej' Odagutan?


Egbe:  Awe O?... nin' eje; ... 

           Nin'ej' Odagutan fun okan? 

           Aso re ha funfun? O si mo laulau? 

           A we o nin' ej' Odagutan?


'Wo mba Olugbala rin lojoojumo?

 Awe o nin'ej' Odagutan? 

'Wo sinmi le Ẹniti a kan mo 'gi 

Awe o nin' ej' Odagutan?



Aso-re funfun lati pad' Oluwa?

O mo lau nin' ej' Odagutan?

Okan re mura fun 'le didan loke?

K'a wę o nin' ej' Odagutan.



Bo ewu eeri-ese si apakan, 

K'o si we nin' ej' Odagutan? 

Isun kan nsan fun gbogbo okan aimo, 

Joo, lo we nin' ej' Odagutan.

ITAN IYANU TIFE

 "Mo mu ihinrere ayo nla fun nyin wa" (Luku 2:10) 

English:  Wonderful Story of Love



ITAN iyanu ti 'fe! 

So fun mi leekan sii!

Itan iyanu ti 'fe!

Ti ndun leti kikan! 

Awon angeli rohin re, 

awon oluso si gbagbo, 

Elese iwo ki y'o gbo? 

Itan iyanu ti 'fe!


Egbe: I... ya....nu! I... ya... nu! 

           I.... ya.... Nu! Itan iyanu ti 'fe!



Itan iyanu ti 'fe! 

Bi 'wo tilę sako; 

Itan iyanu ti 'fe! 

sibę npe loni! 

Lat' ori oke Kalfari, 

lati orisun Kristali; 

Lati isedale aiye; 

Itan iyanu ti 'fe!"



Itan iyanu ti 'fe! 

Jesu ni isinmi; 

Itan iyanu ti 'fe! 

Fun awon oloooto! 

T'o sinmi ni 'Iu nla orun, 

pel' awon t'o saaju wa lo; 

Nwon nko orin ayo orun; 

Itan iyanu ti 'fe!

AFOPE FOLORUN

"Olorun yi Olorun wa ni lai ati lailai" (Orin Dafidi 49:14)




Afope folorun,

L'okan ati ohun wa, 

Eni s' ohun 'yanu,

 N'nu Enit' araiye nyo, 

Gbat' a wa l'omowo

On na l' o ntoju wa, 

O sinf ebun ife

Se 'to ju wa sibę.



Oba Onibu ore,

Ma fi wa silę lailai,

Ayo ti ko lopin

On' bukun y'o je ti wa, 

Pa wa mo n'nu ore, 

To wa gb'a ba damu,

Yo wa ninu ibi

L'a iye ati l'orun.



K'af'iyin on ope F'Olorun Baba, 

Qmo, Ati Emi Mimo, 

Tio gajulo l'orun, 

Olorun kan lailai, 

T'aiye at' orun mbo 

Be l'Owad' isiyi, 

Beni y'o wa lailai.

GBA AIYE MI OLUWA

  "Bio se emi ati ile mi ni, Oluwa li awa o maa sin" (Josua 24:15)      Take my Life, and Let it be             G. H. 12 GBA aiye ...