"Emi ni yi, ran mi" (Isaiah 6:8)
PELU ayo l' ao sisę fun Jesu,
Pelu ife l'a of owo wa se
Ise t'Olugbala ba yan fun wa,
L'ododo l'a o sise, 'ransę wa.
Egbe: Sise fun Jesu,
L'ayo l' ao lo, l'ayo l'a o lo
Sise fun Jesu;
Ninu ogba Re l'aye.
Pelu adun li a o so itan naa,
Ti 'fe nla Re s' awon enia,
Kristi itansan Ogo ti Baba,
Lofe l'On y'o fi 'bukun gun wa.
Pelu 'reti l' ao sise f Oluwa,
Ao fi otito rin lona Rę!
Aot' asako sodo Olugbala,
A o f'Od'agutan han elęsę.
No comments:
Post a Comment