Wednesday, September 1, 2021

PELU AYO LA O SISE FUN JESU

"Emi ni yi, ran mi" (Isaiah 6:8)


PELU ayo l' ao sisę fun Jesu, 

Pelu ife l'a of owo wa se 

Ise t'Olugbala ba yan fun wa, 

L'ododo l'a o sise, 'ransę wa.



Egbe:       Sise fun Jesu,

                 L'ayo l' ao lo, l'ayo l'a o lo 

                 Sise fun Jesu; 

                 Ninu ogba Re l'aye.



Pelu adun li a o so itan naa, 

Ti 'fe nla Re s' awon enia, 

Kristi itansan Ogo ti Baba, 

Lofe l'On y'o fi 'bukun gun wa.



Pelu 'reti l' ao sise f Oluwa, 

Ao fi otito rin lona Rę! 

Aot' asako sodo Olugbala,  

A o f'Od'agutan han elęsę.


SISE TORI ORU N BO

"Oru mbo wa nigbati enikan li yio le sise" (Johannu 9:4) 

Work for the Night is Coming            S.S. & S. 778



SISE 'tori oru mbo! Sise Ii owuro 

Sisę nigba 'iri nse, sisę n'nu 'tanna, 

Sisę ki osan to po, sisę nigb' oorun nran, 

Sise 'tori oru mbo, 'gba 'se o pari.



Sise 'tori oru mbo! Sisę losan gangan, 

F' akoko rere fun 'se, isinmi daju; 

F'olukuluku igba, ni nkan lati pamo; 

Sise 'tori oru mbo, 'gba 'se o pari.



Sise 'tori oru mbo! Oorun ferę won a, 

Sise 'gbati 'mole wa, ojo bu lo tan; 

Sisę titi de opin, sisee titi d'ale; 

Sise 'gbati 'le ba su, 'gba 'se o pari.


ISORO LOTUN LOSI

 "E tujuka, mo ti segun aiye" (Johannu 16:33) 

 Southland Spirituals           12


ISORO l'otun, l'osi; a ko si le mo ona 

T'Oluwa y'o gba to wa, de ile ileri naa, 

Sugbon y'o s' amona wa, a o te le 'E titi 'ku, 

Y'o si han fun wa nigbati o ba se.



Egbe:    Nigboose, li owuro naa;

             Tom' Olorun y'o pejo si 'Ie;

             Ay'o maa so 'tan bi a ti,segun, 

             Y'o si han fun wa nigbati, o base.



Opo'gba l'anse aini awon nkan t' o ye k' ani, 

Nkan bii 'bugbe at' onje. ojo ati 'lerere' 

Sugb' angbekel' Oluwa, ati gege b" oro 

Re Y'o si han fun wa nigbati o base.



Opo 'gba l' a bo sinu, idanwo ati 'kekun, 

Okan wa a si gbogbę, fun asise wa wonyi; 

Asi wa ya wa lenu, 'tor' a ti sa ipa wa, 

Y'o si han fun wa nigbati o ba se.



Olugbala je Oba; y' o si maa to wa s' ona. 

Ohunkohun ti 'danwo le je, saa gbeke re le E

Oti segun ku fun wa, O se leri fun wape

Yo si han fun wa nigbati o ba se.

ORE-OFE BO TI DUN TO

  "Omo enia de lati wa awon ti o nu" (Luku 19:10)


Amazing Grace  S.S. & S. 892


ORE-OFE b'o ti dun to!

T'o gba em' aosi; 

Moti sonu, o wa mi ri, 

O si si mi loju.



Or' ofę ko mi ki ng beru, 

O si l' eru mi lo; 

B'ore-ofe naa ti han to 

Nigba' mo ko gbagbo!



Opo ewu ati 'dekun, 

Ni mo ti la koja; 

Or'-ofe npa mi mo d'oni,

Y'o si sin mi de 'le.



Nje 'gbat' ara at' okan yi, 

At'emi ba si pin, 

Ngo gb' ayo' at' alaafia, 

Loke orun lohun. Amin.

NGO HAKU NI OWO OFO

 "Awon ti o si nyi opolopo pada si ododo yio maa tan" (Dafidi 12:3) 

Must I Go-and Empty-handed?                                   S.S. & S.789



NGO HAku ni owo ofo,

Kin'g'ba Oluwa mi 'bee? 

Ng 'ko tii fun U ni 'se ojo kan, 

Ikogun fun On ko si.



Egbe:      Ngo ha ku ni owo ofo; 

               Ngo ha r' Oluwa mi be? 

               Ko si 'se kan lati fi fun U, 

               Kin pade Re low' o fo?



Iku ko le d' eru ba mi, 

'Tori Jesu gba mi la, 

Ki ng pade Rę lowo ofo, 

Iro yi mb' okan mi ję.



Aa! Akoko t' o ti sonu, 

Emi 'ba le pe e pada, 

Ng 'ba fi i fun Oluwa mi, 

L'ayo ng ba se ifę Rę.



Eji, ennyin Onigbagbo, 

K'e sise ki 'le t'o su, 

Kiigbe-aiye nyin to tan, 

So eso fun Oluwa.

ITAN IYANU TI FE

"Mo mu ihinrere ayo nla fun nyin wa" (Luku 2:10)

Wonderful Story of Love



ITAN iyanu ti 'fe! So fun mi leekan sii!

Itan iyanu ti 'fe! Ti ndun leti kikan! 

Awon angeli rohin rę, awon oluso si gbagbo, 

Elese iwo ki y'o gbo? Itan iyanu ti 'fe!



I...ya....nu! I... ya...nu! 

I.... ya.... Nu! Itan iyanu ti 'fe!



Itan iyanu ti 'fe! Bi 'wo tilę sako; 

Itan iyanu ti 'fe! sibę npe loni! 

Lat' ori oke Kalfari, lati orisun Kristali; 

Lati isedale aiye; Itan iyanu ti 'fe!"



Itan iyanu ti 'fe! Jesu ni isinmi; 

Itan iyanu ti 'fe! Fun awon oloooto! 

T'o sinmi ni 'Iu nla orun, pel' awon t'o saaju wa lo; 

Nwon nko orin ayo orun; Itan iyanu ti'fe!

JESU NFE GBA ELESE

 "Nigbati awa je elese, Kristi ku fun wa" (Romu 5:8)

Christ Receiveth Sinful Men                S.S. & S.390


JESU nfe gba elese; 

Kede re fun gbogb'eda, 

T'o yapa ona orun 'le, 

At' awon ti njafara.



Egbe:      K'orin... k'o si tun uko... 

               Kristi ngba...gbogbo elese.... 

               Je ki 'hin...naa daju pe... 

               Kristi ngba gbogb' elese.


Wa, y'o fun o ni 'stnmi, 

Gba A gbo, oro Re daju, 

'Y'o gb'elese t'o buru, 

Kristi ngba gbogb' elese.



Ọkan mi ko l'ębi mo? 

Mo mo niwaju ofin; 

Enit' o ti wę mi mọ, 

Ti san gbogbo 'gbese mi.



Kristi ngba gbogb' elese,

An' emi to deseju; 

T'a wę mo patapata, 

Mo d' eni 'joba orun.

GBA AIYE MI OLUWA

  "Bio se emi ati ile mi ni, Oluwa li awa o maa sin" (Josua 24:15)      Take my Life, and Let it be             G. H. 12 GBA aiye ...